A d’ifá fún Odù,
ti o ni on ó fi apèrè jókòó
Nwon ni iwo Odù ti ó bá fi apèrè jókòó,
nwon ni o ó rúbo
O ni kini on ó rúbo fún?
Nwon ni nitori awon omo re ni ki o rúbo fún
Nwon ni, ki Odù ó rú eyin’die méwa
Nwon ni, ki ó tójú igbin méwa
Nwon ni, ki ó si tójú egbàáwa
Odù rúbo
Nigbati Odù rúbo tán,
nwon se’fá fún un, Odù fi apèrè jókòó
Nwon ni, iwo Odù ti ó bá ti fi apèrè yii jókòó,
nwon ni, o ó dàgbà, o ó darúgbó
Nwon ni, ti o jé wi pé gbogbo ori rè ni yio funfun,
ti o ó si darúgbó púpò
Nwon ni ti o ó pe l’aiyé,
ti o ò si ni tètè kú,
iwo Odù
Nigbati Odù kò tètè kú
Odù mbe l’alafi a
Nigbati o wá yá, Odù wa dàgbà dàgbà
O di wi pé ti nwon bá mbi Odù léèrè òrò,
dé ibi ti o dàgbà dé
Odù kò mò nkankan mó
Ninú ki o máa gbó ohùn òrò miran ti nwon bá so fún un
Ninu kó si máa gbo òrò miran ti nwon bá so fún un
Nigbati o wá yá ni Odù wá pè gbogbo awon omo rè
O ni enyin omo on,
o ni àgbà dé si on
O ni ti nwon bá wá fé bi on léèrè òrò,
o ni on ó wá wá ohun ti nwon o máa bi léèrè òrò sikeji on
Ni Odù l’ó bá lo
Ni Odù bá tún padà,
l’o bá lo rèé ké si gbogbo awon egbe rè jo
125
Nigba náà ti Odù ó fi ni igbá
Awon alásaro rè ti won jojo ro òrò ki igbá ó wà fún on
Awon mererin ni
Eni ti o wá nibè n’ijó náà ni Obàrisà
Léhin ti o ké si Obàrisà, o si ké si Babalúaiyé
Nigbati o ké si Babalúaiyé, o si ké si Ògún náà
Nigbati o ké si Ògún tán, o si ké si Odùdúà
Odùdúà l’o s’ikerin nwon
Do'stlaringiz bilan baham: |